IMURASILE
A le ko orin kan.
A le lo Gbolohun (Ese Oro Olorun) ti o ba ye (Wo Afikun III)
Oludari: Emi yoo maa yin Olorun nigba gbogbo
Ijo: Iyin Re yoo maa wa lenu mi titi lae.
Oludari: E gbe oluwa ga pelu mi
Ijo: E je ki a jumo gbe Oruko Re leke
Oludari: Eyi ni ojo ti Oluwa da
Ijo: Awa yoo maa yo, inu wa yoo si maa dun ninu re.
TABI
ADFENTI/LENTI
Oludari: Olubukun ni Oluwa ti O n dari ese wa ji
Ijo: Aanu Olorun duro laelae.
TABI
KERESIMESI
Oludari: A bi Kristi Oluwa fun wa loni
Ijo: E wa ka lo juba Re.
TABI
Ni Ojo Ajinde titi di Pentikosti (Isinmi Funfun)
Oludari: Aleluya! Kristi jinde
Ijo: O jinde nitooto, Aleluya!
TABI
Ni Ojo Pentikosti (Isinmi Funfun)
Oludari: Oluwa n be ni ihin
Ijo: Emi Re n be pelu wa.